Skip to content

Ramah

13 verses

31.8300, 35.1800 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ramah

  1. Wọ́n sì dìde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú Olúwa, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rama: Elkana si mọ Hana aya rẹ̀: Olúwa sì rántí rẹ̀.

  2. Elkana sì lọ sí Rama, sí ilé rẹ̀, ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Olúwa níwájú Eli àlùfáà.

  3. Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rama, níbí tí ilé rẹ̀ wà, ó sì túnṣe ìdájọ́ Israẹli níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama.

  5. Nígbà náà ni Samuẹli lọ sí Rama, Saulu sì gòkè lọ sí ilé e rẹ̀ ní Gibeah tí Saulu.

  6. Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo òróró, ó sì ta á sí i ní orí ní iwájú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, láti ọjọ́ náà lọ, Ẹ̀mí Mímọ́ Olúwa wá sí orí Dafidi nínú agbára. Samuẹli sì lọ sí Rama.

  7. Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀.

  8. Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,”

  9. Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rama ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Seku. Ó sì béèrè, “Níbo ni Samuẹli àti Dafidi wà?” Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Naioti ní Rama.”

  10. Saulu sì lọ sí Naioti ni Rama. Ṣùgbọ́n, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń sọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.

  11. Nígbà náà ni Dafidi sá kúrò ní Naioti ti Rama ó sì lọ sọ́dọ̀ Jonatani ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?”

  12. Samuẹli sì kú; gbogbo ènìyàn Israẹli sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì sọkún rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ilé rẹ̀ ní Rama. Dafidi sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Parani.

  13. Samuẹli sì ti kú, gbogbo Israẹli sì sọkún rẹ̀, wọ́n sì sin ín ní Rama ní ìlú rẹ̀. Saulu sì ti mú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ọkùnrin, àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀ obìnrin kúrò ní ilẹ̀ náà.