Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Synagogues

57 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀.

  2. Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,”

  3. Saulu sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú Dafidi wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Samuẹli dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Saulu àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀.

  4. Wọ́n sì sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. Saulu tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní sọtẹ́lẹ̀.

  5. Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rama ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Seku. Ó sì béèrè, “Níbo ni Samuẹli àti Dafidi wà?” Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Naioti ní Rama.”

  6. Saulu sì lọ sí Naioti ni Rama. Ṣùgbọ́n, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń sọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.

  7. Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Saulu náà wà lára àwọn wòlíì ni?”

  8. “Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù tuntun tàbí ọjọ́ ìsinmi.” Ó wí pé, “Gbogbo rẹ̀ ti dára.”

  9. gbogbo àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ bí ẹnìkan ní gbangba ìta níwájú ibodè omi. Wọ́n sọ fún Esra akọ̀wé pé kí ó gbé ìwé òfin Mose jáde, èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún Israẹli.

  10. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ni àlùfáà Esra gbé ìwé òfin jáde ní iwájú ìjọ ènìyàn, èyí tí ó jẹ́ àpapọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àti gbogbo àwọn ènìyàn tí wọ́n le è gbọ́ ọ ní àgbọ́yé.

  11. Ó kà á sókè láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán bí ó ti kọjú sí ìta ní iwájú ibodè omi ní ojú u gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ènìyàn tókù tí òye le è yé tí wọ́n wà níbẹ̀. Gbogbo ènìyàn sì fetísílẹ̀ sí ìwé òfin náà pẹ̀lú ìfarabalẹ̀.

  12. Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí.

  13. Esra ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn sì le rí í nítorí ó dúró níbi tí ó ga ju gbogbo ènìyàn lọ; bí ó sì ti ṣí ìwé náà, gbogbo ènìyàn dìde dúró.

  14. Esra yin Olúwa, Ọlọ́run alágbára; gbogbo ènìyàn gbé ọwọ́ wọn sókè, wọ́n sì wí pé, “Àmín! Àmín!” Nígbà náà ni wọ́n wólẹ̀ wọ́n sì sin Olúwa ní ìdojúbolẹ̀.

  15. Àwọn Lefi—Jeṣua, Bani, Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodiah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani àti Pelaiah—kọ́ wọn ni òfin náà bí àwọn ènìyàn ṣe wà ní ìdúró síbẹ̀.

  16. Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké.

  17. Esra kà nínú ìwé òfin Ọlọ́run, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, láti ọjọ́ kìn-ín-ní dé ọjọ́ ìkẹyìn. Wọ́n ṣe àjọyọ̀ àjọ náà fún ọjọ́ méje, ní ọjọ́ kẹjọ wọ́n ní àpéjọ, ní ìbámu pẹ̀lú òfin.

  18. Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin Olúwa Ọlọ́run wọn.

  19. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé, “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ.

  20. Ní ọjọ́ náà ni a ka ìwé Mose sókè sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn, nínú rẹ̀ ni a ti rí i tí a kọ ọ́ sílẹ̀ pé a kò gbọdọ̀ gba àwọn ará a Ammoni tàbí àwọn ará a Moabu sí àárín ìjọ ènìyàn Ọlọ́run láéláé.

  21. Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

  22. Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn.

  23. “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún.

  24. Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu.

  25. Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn,