Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Judges of Israel

42 ẹsẹ · 17 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú.

  2. Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa.

  3. Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n.

  4. Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.

  5. Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Otnieli ọmọ Kenasi àbúrò Kalebu tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

  6. Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, òun sì ṣe ìdájọ́ Israẹli, ó sì síwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kuṣani-Riṣataimu ọba Aramu lé Otnieli lọ́wọ́, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ sì borí Kuṣani-Riṣataimu.

  7. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Otnieli ọmọ Kenasi sì kú.

  8. Lẹ́yìn ikú Abimeleki, ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Isakari tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, dìde láti gba Israẹli sílẹ̀. Ní Ṣamiri tí ó wà ní òkè Efraimu ni ó gbé.

  9. Ó ṣe àkóso Israẹli ní ọdún mẹ́tàlélógún. Nígbà tí ó kú wọ́n sìn ín sí Ṣamiri.

  10. Jairi ti ẹ̀yà Gileadi ni ó dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó ṣàkóso Israẹli ní ọdún méjìlélógún.

  11. Àwọn ọgbọ̀n ọmọ tí ó n gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n ṣe àkóso ọgbọ̀n ìlú ní Gileadi, tí a pe orúkọ wọn ní Hafoti-Jairi títí di òní.

  12. Nígbà tí Jairi kú wọ́n sin ín sí Kamoni.

  13. Àwọn ọkùnrin Efraimu pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí ìhà àríwá, wọ́n sì bi Jefta pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ammoni jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò sun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”

  14. Jefta dáhùn pé, “Èmi àti àwọn ènìyàn ní ìyọnu ńlá pẹ̀lú àwọn ará Ammoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo pè yín, ẹ̀yin kò gbà mí sílẹ̀ ní ọwọ́ wọn.

  15. Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀yin kò gbà mí, mo fi ẹ̀mí mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ammoni jà, Olúwa sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”

  16. Nígbà náà ni Jefta kó gbogbo ọkùnrin Gileadi jọ, ó sì bá Efraimu jà. Àwọn ọkùnrin Gileadi sì kọlù Efraimu, nítorí wọ́n ti sọtẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gileadi jẹ́ àsáwọ̀ àwọn ará Efraimu àti ti Manase.”

  17. Àwọn ará Gileadi gba à bá wọ odò Jordani tí wọ́n máa gbà lọ sí Efraimu, nígbàkígbà tí àwọn ará Efraimu bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sálọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gileadi yóò bi í pé, “Ṣé ará Efraimu ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,”

  18. wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣibolẹti.’ ” Tí ó bá ní, “Sibolẹti,” torí pé kò ní mọ̀ ọ́n pé dáradára, wọ́n á mú un wọn, a sì pa á ni à bá wọ odò Jordani. Àwọn ará Efraimu tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì (42,000) ọkùnrin.

  19. Jefta ṣe ìdájọ́ Israẹli ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jefta ará Gileadi kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gileadi.

  20. Lẹ́yìn Jefta, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

  21. Ó ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ibsani ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje.

  22. Lẹ́yìn náà ni Ibsani kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹtilẹhẹmu.

  23. Lẹ́yìn rẹ̀, Eloni ti ẹ̀yà Sebuluni ṣe àkóso Israẹli fún ọdún mẹ́wàá.

  24. Eloni sì kú, wọ́n sì sin ín sí Aijaloni ní ilẹ̀ Sebuluni.

  25. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hileli tí Piratoni n ṣe àkóso Israẹli.