Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reproof

165 ẹsẹ · 70 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ.

  2. Pípé ni òfin Olúwa, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí Olúwa dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.

  3. Ìlànà Olúwa tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ Olúwa ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.

  4. Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ Olúwa dájú òdodo ni gbogbo wọn.

  5. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ.

  6. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.

  7. Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀ fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀, ìwọ a mú ẹwà rẹ parun bí kòkòrò aṣọ; nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

  8. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́; ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí, èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.

  9. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,

  10. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ.

  11. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ.

  12. Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.

  13. Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mi ní orí. Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.

  14. Níwọ́n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,

  15. Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!

  16. Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè.

  17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.

  18. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

  19. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

  20. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.

  21. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

  22. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

  23. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

  24. Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

  25. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.