Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reproof: General references

41 ẹsẹ · 70 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

  2. Jẹ́ kí olódodo lù mí, ìṣeun ni ó jẹ́: jẹ́ kí ó bá mi wí, ó jẹ́ òróró ní orí mi. Tí kì yóò fọ́ mi ní orí. Síbẹ̀ àdúrà mi wá láìsí ìṣe àwọn olùṣe búburú.

  3. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.

  4. Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ. Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;

  5. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà.

  6. Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.

  7. Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di tálákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.

  8. Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

  9. Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.

  10. Ẹlẹ́gàn kò fẹ́ ẹni tí ń ba wí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.

  11. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.

  12. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.

  13. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.

  14. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

  15. Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n, nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.

  16. Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

  17. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

  18. Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

  19. Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

  20. Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.

  21. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

  22. Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.

  23. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò.

  24. Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà.

  25. Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.