Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reproof

165 ẹsẹ · 70 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i.

  2. Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyàn ju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀.

  3. Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ sí i.

  4. Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn, òpè a máa kọ́gbọ́n, nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.

  5. Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

  6. Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀.

  7. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

  8. Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.

  9. Òtítọ́ ni ọgbẹ́ ọ̀rẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹnukonu ọ̀tá ni ẹ̀tàn.

  10. Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.

  11. Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.

  12. Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀.

  13. Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.

  14. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

  15. Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,

  16. Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú; wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà, gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n. Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́ àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

  17. “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn, àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  18. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’

  19. Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí.

  20. Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.’

  21. Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀ nítorí pé wọ́n ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn.

  22. Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n.

  23. Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n.

  24. “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.

  25. “Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí.