Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Reproof

165 ẹsẹ · 70 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ máa kíyèsára yín. “Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín.

  2. Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”

  3. Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Peteru, àkùkọ kì yóò kọ lónìí tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”

  4. Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà?

  5. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́,

  6. Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì wárìrì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.

  7. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí èròkerò fi ń sọ nínú ọkàn yín?

  8. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhìn-ín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”

  9. Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú.

  10. Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

  11. Jesu dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”

  12. Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.” Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”

  13. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ, nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

  14. Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́,

  15. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?

  16. Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”

  17. Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

  18. “Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!

  19. Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

  20. Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

  21. Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín.

  22. Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

  23. Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí?

  24. Ìròyìn rẹ ń tàn kalẹ̀ pé ìwà àgbèrè wa láàrín yín, irú àgbèrè tí a kò tilẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà pé, ẹnìkan nínú yín ń fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀.

  25. Ẹ̀yin ń ṣe ìgbéraga! Ẹ̀yin kò kúkú káàánú kí a lè mú ẹni tí ó hu ìwà yìí kúrò láàrín yín?