Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets

655 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni wọ̀nyí olúwa mi?” Angẹli tí ń ba mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Èmi ó fi ohun tí àwọn wọ̀nyí jẹ́ hàn ọ́.”

  2. Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.

  3. Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni.

  4. Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?” Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”

  5. Nítorí kíyèsi i, èmi ó gbọn ọwọ́ mi sí orí wọn, wọn yóò sì jẹ́ ìkógun fún ìránṣẹ́ wọn: ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi.

  6. Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  7. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.

  8. Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ Olúwa sí Israẹli láti ẹnu Malaki.

  9. Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.

  10. Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ̀, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

  11. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè àmì; ṣùgbọ́n kò sí àmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe àmì Jona wòlíì.

  12. Inú bí wọn sí i. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.”

  13. Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú.

  14. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  15. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.

  16. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.

  17. Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro.

  18. “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),

  19. Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn.

  20. Ó sọ fún wọn pé, “Àwa ń gòkè lọ Jerusalẹmu, a ó sì fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà.

  21. Wọn yóò fi ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàṣán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”

  22. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.

  23. Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

  24. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.

  25. Ó sì ṣe, nígbà tí Elisabeti gbọ́ kíkí Maria, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Elisabeti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́,