Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets: Specially raised up on occasions of emergency
Àwọn ẹsẹ nípa Specially raised up on occasions of emergency
Olúwa wà pẹ̀lú Samuẹli bí ó ṣe ń dàgbà, kò sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kùnà.
Gbogbo Israẹli láti Dani títí dé Beerṣeba mọ̀ pé a ti fa Samuẹli kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wòlíì Olúwa.
Olúwa sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara hàn án ní Ṣilo, nítorí Olúwa ti fi ará hàn án fún Samuẹli ní Ṣilo nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.
Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?” Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé, “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
“Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n, kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀. Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”