Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets: Wore a coarse dress of hair-cloth
Àwọn ẹsẹ nípa Wore a coarse dress of hair-cloth
Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.” Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.”
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.
Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.”