Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets: Called Seers

11 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Called Seers

  1. Samuẹli dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.

  2. Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari.

  3. Dafidi sì dìde ní òwúrọ̀, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Gadi wòlíì wá, aríran Dafidi wí pé,

  4. Olúwa kìlọ̀ fún Israẹli àti Juda nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi paláṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán sí i yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

  5. Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn.

  6. Ní ti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba ọba Dafidi, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, a kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Samuẹli aríran, ìwé ìrántí ti Natani wòlíì àti ìwé ìrántí ti Gadi aríran,

  7. Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati?

  8. Fún tí iṣẹ́ ìjọba Rehoboamu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Ṣemaiah wòlíì àti ti Iddo, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀síwájú ogun jíjà sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu.

  9. Pẹ̀lúpẹ̀lú Hesekiah ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi, láti fi ọ̀rọ̀ Dafidi àti ti Asafu aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.

  10. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé, “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!” Àti fún àwọn wòlíì, “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́! Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa, ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

  11. Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”