Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets: Often put them to death

6 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Often put them to death

  1. Ṣé Olúwa mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jesebeli ń pa àwọn wòlíì Olúwa? Mo fi ọgọ́rùn-ún wòlíì Olúwa pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn.

  2. Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.”

  3. Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú.

  4. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  5. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.

  6. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.