Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets

655 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sekariah baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọtẹ́lẹ̀, ó ní:

  2. (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tipẹ́tipẹ́),

  3. Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

  4. A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa.

  5. Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin.

  6. Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá;

  7. tí Annasi òun Kaiafa ń ṣe olórí àwọn àlùfáà, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Johanu ọmọ Sekariah wá ní ijù.

  8. A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:

  9. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.

  10. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní Israẹli nígbà ọjọ́ wòlíì Elijah, nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo.

  11. Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Elijah sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sarefati, ìlú kan ní Sidoni.

  12. Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Israẹli nígbà wòlíì Eliṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Naamani ará Siria.”

  13. Kí a lè béèrè ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì gbogbo, tí a ti ta sílẹ̀ láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, lọ́wọ́ ìran yìí;

  14. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!

  15. Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé, a ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mose, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Saamu, nípasẹ̀ mi.”

  16. Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu.

  17. Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”

  18. Nítorí Jesu tìkára rẹ̀ ti jẹ́rìí wí pé, Wòlíì kì í ní ọlá ní ilẹ̀ òun tìkára rẹ̀.

  19. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

  20. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

  21. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

  22. Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joẹli wá pé:

  23. Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò.

  24. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ wòlíì, àti bí ó mọ́ pé, Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún òun nínú ìbúra pé nínú irú-ọmọ inú rẹ̀, òun yóò mú ọ̀kan jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀.

  25. Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà.