Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prophets

655 ẹsẹ · 128 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.

  2. Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,

  3. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i,

  4. Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn.

  5. Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì,

  6. àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu,

  7. tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá.

  8. Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà.

  9. Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú.

  10. A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn, wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró;

  11. àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún. Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

  12. Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà,

  13. nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.

  14. Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.

  15. Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀.

  16. Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e.

  17. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.

  18. Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn.

  19. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí.

  20. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Enoku, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Adamu, sọtẹ́lẹ̀ nípa wọn pé, “Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́,

  21. Ìfihàn ti Jesu Kristi, tí Ọlọ́run fi fún un, láti fihàn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ohun tí kò le ṣàìṣẹ ní lọ́ọ́lọ́ọ́; ó sì ránṣẹ́, ó sì fi í hàn láti ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fún Johanu, ìránṣẹ́ rẹ̀,

  22. Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.

  23. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ohùn angẹli keje, nígbà tí yóò ba fún ìpè, nígbà náà ni ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí o tí sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì ni a ó mú ṣẹ.”

  24. Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó lé ọgọ́ta (1,260) nínú aṣọ ọ̀fọ̀.”

  25. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.” Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”