Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests

407 ẹsẹ · 86 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé Olúwa di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu.

  2. Àwọn àlùfáà. Àwọn ọmọ Jedaiah (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje (973)

  3. Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì (1,052)

  4. Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247)

  5. Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017).

  6. Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.

  7. Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.

  8. Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ́gbẹ̀rún (61,000) ìwọ̀n dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) fàdákà àti ọgọ́rùn-ún ẹ̀wù àlùfáà.

  9. Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́.

  10. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

  11. Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) mina fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

  12. “Síwájú sí i, àwa yóò mú àkọ́so oúnjẹ ilẹ̀ wa ti ọrẹ oúnjẹ, ti gbogbo èso àwọn igi àti ti wáìnì tuntun wa àti ti òróró wá sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ilé Ọlọ́run wa àti fún àwọn àlùfáà. Àwa yóò sì mú ìdámẹ́wàá ohun ọ̀gbìn wá fún àwọn ọmọ Lefi, nítorí àwọn ọmọ Lefi ni ó ń gba ìdámẹ́wàá ní gbogbo àwọn ìlú tí a ti ń ṣiṣẹ́.

  13. Àlùfáà tí o ti ìdílé Aaroni wá ni yóò wá pẹ̀lú àwọn ọmọ Lefi nígbà tí wọ́n bá ń gba ìdámẹ́wàá, àwọn ọmọ Lefi yóò sì mú ìdámẹ́wàá ti ìdámẹ́wàá náà wá sí ilé Ọlọ́run, sí yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí inú ilé ìṣúra.

  14. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

  15. “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn.

  16. Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà, Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa. Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá, èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn. Wòlíì àti Àlùfáà ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

  17. “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.

  18. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Anatoti láti ọwọ́ Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tàdínlógún fún un.

  19. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó. Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí. Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ Olúwa?

  20. Nígbà tí wọ́n bá lọ sì àgbàlá òde níbi tí àwọn ènìyàn wà, wọn gbọdọ̀ bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ki wọn sì fi wọn sílẹ̀ sí àwọn yàrá mímọ́ náà, kí wọn kí ó sì wọ ẹ̀wù mìíràn, wọn kì yóò sì fi ẹ̀wù wọn sọ àwọn ènìyàn di mímọ́.

  21. Àlùfáà kankan kò gbọdọ̀ mu ọtí nígbà tí ó bá wọ àgbàlá tí inú.

  22. “Nítorí ètè àlùfáà ní òye láti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni ìránṣẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  23. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  24. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan.

  25. Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti.