Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests: No blemished or defective persons could be consecrated

7 ẹsẹ · 86 abala

Àwọn ẹsẹ nípa No blemished or defective persons could be consecrated

  1. “Sọ fún Aaroni pé, ‘Ẹnikẹ́ni nínú irú-ọmọ rẹ̀ ní ìran-ìran wọn, tí ó bá ní ààrùn kan, kí ó má ṣe súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ ohun jíjẹ sí Ọlọ́run rẹ̀.

  2. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.

  3. Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,

  4. tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.

  5. Ẹnikẹ́ni tí ó ní àbùkù nínú irú-ọmọ Aaroni àlùfáà kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ tí fi iná sun sí Olúwa. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí láti rú ẹbọ àkàrà sí Ọlọ́run rẹ̀.

  6. Ó lè jẹ́ oúnjẹ Ọlọ́run rẹ̀ tàbí èyí tí ó mọ́ jùlọ, ṣùgbọ́n torí pé ó ní àbùkù kò gbọdọ̀ súnmọ́ ibi aṣọ títa tàbí pẹpẹ.

  7. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ba ibi mímọ́ mi jẹ́ torí pé, Èmi Olúwa ló ti sọ wọ́n di mímọ́.’ ”