Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests: Purification by blood of the consecration ram

4 ẹsẹ · 86 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Purification by blood of the consecration ram

  1. Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká.

  2. Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.

  3. Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

  4. Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.