Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests: Offering first fruits

4 ẹsẹ · 86 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Offering first fruits

  1. “Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.

  2. Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.

  3. Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.”

  4. Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ.