Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests: Lighting and trimming the lamps of the sanctuary
Àwọn ẹsẹ nípa Lighting and trimming the lamps of the sanctuary
“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn kí ó mú òróró olifi dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn síbẹ̀.
Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde aṣọ ìkélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Aaroni àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ láti alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú Olúwa: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.
Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́.