Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priests: Blessing the people
Àwọn ẹsẹ nípa Blessing the people
“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé,
“ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín, kí ó sì pa yín mọ́.
Kí Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
Kí Olúwa bojú wò yín, kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’
“Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Israẹli, Èmi ó sì bùkún wọn.”