Skip to content

Geba

14 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Gaba

31.8500, 35.2500 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Geba

  1. Kefari, Ammoni, Ofini àti Geba; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn.

  2. Láti ara ẹ̀yà Benjamini ni wọ́n ti fún wọn ní: Gibeoni, Geba,

  3. Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!”

  4. Nígbà náà ni Asa ọba kéde ká gbogbo Juda, kò dá ẹnìkan sí, wọ́n sì kó òkúta Rama kúrò àti igi rẹ̀, tí Baaṣa fi kọ́lé. Asa ọba sì fi wọ́n kọ́ Geba ti Benjamini àti Mispa.

  5. Josiah kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Juda ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Geba sí Beerṣeba, níbi tí àwọn àlùfáà ti sun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ti Joṣua, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

  6. Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.

  7. Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:

  8. Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.

  9. Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621)

  10. Rama àti Geba jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621)

  11. Àwọn ọmọ Benjamini láti Geba ń gbé ní Mikmasi, Aija, Beteli àti àwọn ìletò rẹ̀.

  12. láti Beti-Gilgali, àti láti àwọn agbègbè Geba àti Asmafeti, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnra wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

  13. Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé, “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.” Rama mì tìtì Gibeah ti Saulu sálọ.

  14. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba.