Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables

452 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.

  2. ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun, ó bọ́ sí ojúran.

  3. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀.

  4. Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

  5. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”

  6. Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “Rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”

  7. Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

  8. Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

  9. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

  10. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara, ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

  11. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari.

  12. Nítorí Hagari yìí ni òkè Sinai Arabia, tí ó sì dúró fún Jerusalẹmu tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

  13. Ṣùgbọ́n Jerusalẹmu ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.

  14. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Máa yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

  15. Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Isaaki.

  16. Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsin yìí.

  17. Ṣùgbọ́n ìwé mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrúbìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira obìnrin jogún pọ̀.”

  18. Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrúbìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.

  19. Ṣe alábápín pẹ̀lú mi nínú ìpọ́njú, bí ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.

  20. Kò sí ẹni tí ń jagun ti ń fi ohun ayé yìí dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè mú inú ẹni tí ó yàn ni ọmọ-ogun dùn.

  21. Ní ọ̀nà kan náà, bí ẹnikẹ́ni bá sì ń díje bí olùdíje, a kì í dé e ládé, bí kò ṣe bí ó bá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà

  22. Àgbẹ̀ ti ó ń ṣe làálàá ni ó yẹ láti kọ́kọ́ mu nínú àwọn èso.

  23. Ṣùgbọ́n nínú ilé ńlá, kì í ṣe kìkì ohun èlò wúrà àti ti fàdákà nìkan ni ń bẹ, ṣùgbọ́n ti igi àti amọ̀ pẹ̀lú; àti òmíràn sí ọlá, àti òmíràn sí àìlọ́lá.

  24. Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìwọ̀nyí, òun yóò jẹ́ ohun èlò sí ọlá, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó sì yẹ fún ìlò baálé, tí a sì ti pèsè sílẹ̀ fún iṣẹ́ rere gbogbo.

  25. Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí