Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Parables

452 ẹsẹ · 74 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ó sì ṣe, alágbe kú, a sì ti ọwọ́ àwọn angẹli gbé e lọ sí oókan àyà Abrahamu: ọlọ́rọ̀ náà sì kú pẹ̀lú, a sì sin ín;

  2. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

  3. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  4. “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

  5. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’

  6. “Ó sì wí pé, ‘Ǹjẹ́ mo bẹ̀ ọ́, baba, kí ìwọ kí ó rán Lasaru lọ sí ilé baba mi,

  7. nítorí mo ní arákùnrin márùn-ún; kí ó lè rò fún wọn kí àwọn kí ó má ba á wá sí ibi oró yìí pẹ̀lú.’

  8. “Abrahamu sì wí fún un pé, ‘Wọ́n ní Mose àti àwọn wòlíì; kí wọn kí ó gbọ́ tiwọn.’

  9. “Ó sì wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, Abrahamu baba; ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ti inú òkú tọ̀ wọ́n lọ, wọn ó ronúpìwàdà.’

  10. “Ó sì wí fún un pé, ‘Bí wọn kò bá gbọ́ ti Mose àti ti àwọn wòlíì, a kì yóò yí wọn ní ọkàn padà bí ẹnìkan tilẹ̀ ti inú òkú dìde.’ ”

  11. Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀.

  12. Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn.

  13. Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’

  14. “Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn,

  15. Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkígbà dá mi lágara.’ ”

  16. Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!

  17. Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?

  18. Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”

  19. Ó sì pa òwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ara wọn pé, àwọn ni olódodo, tí wọ́n sì ń gan àwọn ẹlòmíràn,

  20. pé, “Àwọn ọkùnrin méjì gòkè lọ sí tẹmpili láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisi, èkejì sì jẹ́ agbowó òde.

  21. Èyí Farisi dìde, ó sì ń gbàdúrà nínú ara rẹ̀ báyìí pé, ‘Ọlọ́run mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí èmi kò rí bí àwọn ará ìyókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòótọ́, panṣágà, tàbí bí agbowó òde yìí.

  22. Èmi ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì ní ọ̀sẹ̀, mo ń san ìdámẹ́wàá ohun gbogbo tí mo ní.’

  23. “Ṣùgbọ́n agbowó òde dúró lókèèrè, kò tilẹ̀ jẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ṣùgbọ́n ó lu ara rẹ̀ ní oókan àyà, ó wí pé, ‘Ọlọ́run ṣàánú fún mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀!’

  24. “Mo wí fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ìdáláre ju èkejì lọ: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, òun ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá sì rẹ̀ ara rẹ̀ sílẹ̀ òun ni a ó gbéga.”

  25. Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.