Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mountains

136 ẹsẹ · 82 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ́run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ. Wò ó, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pa wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Karmeli.

  2. Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”

  3. Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa.

  4. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “Mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.

  5. “Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.

  6. Ṣùgbọ́n Dafidi fi agbára gba ìlú odi Sioni: èyí náà ni í ṣe ìlú Dafidi.

  7. Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.

  8. Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.

  9. Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni.

  10. Mikaiah sì dáhùn pé, “Mo rí gbogbo Israẹli túká kiri lórí àwọn òkè bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, Olúwa sì wí pé, ‘Àwọn wọ̀nyí kò ní olúwa. Jẹ́ kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’ ”

  11. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀ sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.

  12. Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Jerusalẹmu ní ìhà gúúsù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Aṣtoreti ọlọ́run ìríra àwọn ará Sidoni, fún Kemoṣi ọlọ́run ìríra àwọn ará Moabu àti fún Moleki, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ammoni.

  13. Díẹ̀ lára àwọn ará Gadi yà sọ́dọ̀ Dafidi ní ibi gíga ní aginjù. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà ológun tí ó múra fún ogun tí ó sì lágbára láti di asà àti ẹṣin mú. Ojú wọn sì dàbí ojú kìnnìún, wọ́n sì yára bí àgbọ̀nrín lórí àwọn òkè.

  14. Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.

  15. “Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.

  16. Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.

  17. Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.”

  18. Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè.

  19. Òun pẹ̀lú ti kọ́ àwọn ibi gíga lórí àwọn òkè Juda. Ó sì ti fà á kí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ó ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara wọn. Ó sì ti jẹ́ kí wọn ó ṣáko lọ.

  20. Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.

  21. Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.

  22. Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.

  23. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

  24. Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.

  25. Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí rẹ láti ilẹ̀ Jordani wá, láti Hermoni láti òkè Mibsari.