Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mountains: Of difficulties
Àwọn ẹsẹ nípa Of difficulties
Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.
“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”
Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”