Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mountains: Volcanic fires of, alluded to

5 ẹsẹ · 82 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Volcanic fires of, alluded to

  1. Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

  2. Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

  3. “Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

  4. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

  5. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.