Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mountains: Forests

5 ẹsẹ · 82 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Forests

  1. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀ sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.

  2. Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.

  3. “Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.

  4. Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.

  5. Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.”