Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mountains

136 ẹsẹ · 82 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. nítorí gbogbo òkè gíga ńlá ńlá àti àwọn òkè kéékèèké,

  2. Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu, kígbe sí wọn, pè wọ́n láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.

  3. Ẹgbẹ̀rún (1,000) yóò sá nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan; nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún gbogbo yín lẹ ó sálọ, títí a ó fi yín sílẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè, gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”

  4. Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.

  5. Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

  6. Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèké nínú òsùwọ̀n?

  7. “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun, tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá, ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú, a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.

  8. Èmi yóò sọ òkè ńlá àti kékeré di ahoro tí n ó sì gbẹ gbogbo ewéko rẹ̀ dànù, Èmi yóò sọ àwọn odò di erékùṣù n ó sì gbẹ àwọn adágún.

  9. Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.

  10. Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè ńlá mi di ojú ọ̀nà àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.

  11. Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀ a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà; òkè ńlá ńlá àti kéékèèké yóò bú sí orin níwájú yín àti gbogbo igi inú pápá yóò máa pàtẹ́wọ́.

  12. Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá, tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

  13. Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

  14. Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí, o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.

  15. Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn.

  16. “Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,” ni Olúwa wí. “Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ, èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta, Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.

  17. Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.

  18. “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.”

  19. Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́. “Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”

  20. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”

  21. Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

  22. “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá. Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá. Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀, tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké.

  23. Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́, ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀, àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

  24. Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀? Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀? Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná; àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.

  25. Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.