- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commerce
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.
Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.
Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn,
wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.
Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀.
Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.” Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”
Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé,
“Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni.
Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.
Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’
“Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn.
Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”
Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.
“ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”
Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni.
Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.
Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.
Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí.
Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.
Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.
Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.
Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.