Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commerce: Carried on by means of ships
Àwọn ẹsẹ nípa Carried on by means of ships
Hiramu sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ Òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Solomoni.
Wọ́n sì dé Ofiri, wọ́n sì mú irinwó ó lé ogún (420) tálẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Solomoni ọba.
Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.
Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.
Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.
Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.