Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Commerce

82 ẹsẹ · 64 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.

  2. “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.

  3. Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,

  4. wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali!

  5. Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré,

  6. wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’

  7. Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’