Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 13:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Simeoni, Ṣafati ọmọ Hori;

  2. Numeri 13:6nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Juda, Kalebu ọmọ Jefunne;

  3. Numeri 13:7nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Isakari, Igali ọmọ Josẹfu;

  4. Numeri 13:8nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Efraimu, Hosea ọmọ Nuni;

  5. Numeri 13:9nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Benjamini, Palti ọmọ Rafu;

  6. Numeri 13:10nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Sebuluni, Daddieli ọmọ Sodi;

  7. Numeri 13:11nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Manase (ẹ̀yà Josẹfu), Gaddi ọmọ Susi;

  8. Numeri 13:12nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Dani, Ammieli ọmọ Gemalli;

  9. Numeri 13:13nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Aṣeri, Seturu ọmọ Mikaeli.

  10. Numeri 13:14nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Naftali, Nabi ọmọ Fofsi;

  11. Numeri 13:15nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    láti inú ẹ̀yà Gadi, Geueli ọmọ Maki.

  12. Numeri 13:16nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ènìyàn tí Mose rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Hosea ọmọ Nuni ni Mose sọ ní Joṣua.)

  13. Numeri 13:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè.

  14. Numeri 13:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.

  15. Numeri 13:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?

  16. Numeri 13:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)

  17. Numeri 13:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati.

  18. Numeri 13:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.)

  19. Numeri 13:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.

  20. Numeri 13:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀.

  21. Numeri 13:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

  22. Numeri 13:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.

  23. Numeri 13:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.

  24. Numeri 13:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀.

  25. Numeri 13:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.”