- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 37:28nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
“Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wà àti ìgbà tí o wá tí o sì lọ àti bí inú rẹ ṣe ru sí mi.
- Isaiah 37:29nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí pé inú rẹ ru sí mi àti nítorí pé orí kunkun rẹ ti dé etí ìgbọ́ mi, Èmi yóò fi ìwọ̀ mi sí ọ ní imú, àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu, èmi yóò sì jẹ́ kí o padà láti ọ̀nà tí o gbà wá.
- Isaiah 37:30nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
“Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ, ìwọ Hesekiah: “Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnra rẹ̀, àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara rẹ. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè, ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èso wọn.
- Isaiah 37:31nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́kù láti ilé Juda yóò ta gbòǹgbò nísàlẹ̀ yóò sì ṣo èso lókè.
- Isaiah 37:32nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí láti Jerusalẹmu ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá, àti láti òkè Sioni ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.
- Isaiah 37:33nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Asiria, “Òun kì yóò wọ ìlú yìí wá tàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ín Òun kì yóò wá síwájú rẹ pẹ̀lú asà tàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.
- Isaiah 37:34nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá náà ni yóò padà lọ; òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,” ni Olúwa wí.
- Isaiah 37:35nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbà á là, nítorí mi àti nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi!”
- Isaiah 37:36nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà ni angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní i ibùdó àwọn Asiria. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!
- Isaiah 37:37nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Nítorí náà Sennakeribu ọba Asiria fọ́ bùdó ó sì pẹsẹ̀dà. Òun sì padà sí Ninefe, ó sì dúró síbẹ̀.
- Isaiah 37:38nǹkan bí 710 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹmpili Nisroki òrìṣà rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati. Bẹ́ẹ̀ ni Esarhadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
- Isaiah 38:1nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí Olúwa wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”
- Isaiah 38:2nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Hesekiah yí ojú u rẹ̀ sí ara ògiri, ó sì gba àdúrà sí Olúwa,
- Isaiah 38:3nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
“Rántí, Ìwọ Olúwa, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.
- Isaiah 38:4nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Isaiah wá pé,
- Isaiah 38:5nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
“Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí Olúwa wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé, Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.
- Isaiah 38:6nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì gba ìwọ àti ìlú yìí sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí.
- Isaiah 38:7nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
“ ‘Èyí yìí ni àmì tí Olúwa fún ọ láti fihàn wí pé Olúwa yóò mú ìpinnu rẹ̀ ṣẹ.
- Isaiah 38:8nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi yóò mú òjìji oòrùn kí ó padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá nínú èyí tí ó fi sọ̀kalẹ̀ ní ibi àtẹ̀gùn ti Ahasi.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn padà sẹ́yìn ní ìṣísẹ̀ mẹ́wàá sí ibi tí ó ti dé tẹ́lẹ̀.
- Isaiah 38:9nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Ìwé tí Hesekiah ọba Juda kọ lẹ́yìn àìsàn rẹ̀ nígbà tí ó ti gbádùn tán.
- Isaiah 38:10nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi wí pé, “Ní àárín gbùngbùn ọjọ́ ayé mi èmi ó ha kọjá lọ ní ibodè ikú kí a sì dùn mí ní àwọn ọdún mi tí ó ṣẹ́kù?”
- Isaiah 38:11nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi wí pé, “Èmi kì yóò lè tún rí Olúwa mọ́, àní Olúwa, ní ilẹ̀ àwọn alààyè; èmi kì yóò lè síjú wo ọmọ ènìyàn mọ́, tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn tí ó sì ń gbe orílẹ̀ ayé báyìí.
- Isaiah 38:12nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí àgọ́ olùṣọ́-àgùntàn, ilé mi ni a ti wó lulẹ̀ tí a sì gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Gẹ́gẹ́ bí ahunṣọ mo ti ká ayé mi nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni òun sì ti ké mi kúrò lára àṣà; ọ̀sán àti òru ni ìwọ ṣe òpin mi.
- Isaiah 38:13nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi fi sùúrù dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí kìnnìún ó ti fọ́ gbogbo egungun mi; ọ̀sán àti òru ni ìwọ fi ṣe òpin mi.
- Isaiah 38:14nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Èmi dún gẹ́gẹ́ bí àkọ̀ tàbí alápáǹdẹ̀dẹ̀, èmi káàánú gẹ́gẹ́ bí aṣọ̀fọ̀ àdàbà. Ojú mi rẹ̀wẹ̀sì gẹ́gẹ́ bí mo ti ń wo àwọn ọ̀run. Ìdààmú bá mi, Ìwọ Olúwa, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi!”