- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 38:15nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n kí ni èmi lè sọ? Òun ti bá mi sọ̀rọ̀ àti pé òun tìkára rẹ̀ ló ti ṣe èyí. Èmi yóò máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mi nítorí ìpọ́njú ẹ̀mí mi yìí.
- Isaiah 38:16nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Olúwa, nípa nǹkan báwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn ń gbé; àti pé ẹ̀mí mi rí iyè nínú wọn pẹ̀lú. Ìwọ dá ìlera mi padà kí o sì jẹ́ kí n wà láààyè.
- Isaiah 38:17nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni, ní ti pé mo ní ìkorò ńlá. Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́, kúrò nínú ọ̀gbun ìparun; ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
- Isaiah 38:18nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Nítorí pé isà òkú kò le è yìn ọ́, ipò òkú kò le è kọ orin ìyìn rẹ; àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ sínú ọ̀gbun kò lè ní ìrètí fún òtítọ́ rẹ.
- Isaiah 38:19nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Alààyè, àwọn alààyè wọ́n ń yìn ọ́, gẹ́gẹ́ bí èmi ti ń ṣe lónìí; àwọn baba sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa òtítọ́ rẹ.
- Isaiah 38:20nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Olúwa yóò gbà mí là bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò sì kọrin pẹ̀lú ohun èlò olókùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa nínú tẹmpili ti Olúwa.
- Isaiah 38:21nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Isaiah ti sọ pé, “Pèsè ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ (ohun gbígbóná tí a dì mọ́ ojú egbò) kí o sì fi sí ojú oówo náà, òun yóò sì gbádùn.”
- Isaiah 38:22nǹkan bí 718 ṣáájú Kristi
Hesekiah sì béèrè pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé èmi yóò gòkè lọ sí tẹmpili Olúwa?”
- Isaiah 39:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní àkókò náà ni Merodaki-Baladani ọmọ Baladani ọba Babeli fi ìwé àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Hesekiah, nítorí ó gbọ́ pé ó ṣàìsàn ó sì gbádùn.
- Isaiah 39:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Hesekiah gba àwọn ikọ̀ yìí tayọ̀tayọ̀, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà nínú yàrá ìkẹ́rù sí mọ́ hàn wọ́n—fàdákà, wúrà, ohun olóòórùn dídùn, òróró dídára, gbogbo nǹkan ogun rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìṣúra rẹ̀ kò sí ohunkóhun tí ó wà nínú ààfin rẹ̀ tàbí ní ìjọba rẹ̀ tí Hesekiah kò fihàn wọ́n.
- Isaiah 39:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà wòlíì Isaiah lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah ọba ó sì béèrè pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí, níbo ni wọ́n sì ti wá?” “Láti ilẹ̀ jíjìnnà,” ni èsì Hesekiah. “Wọ́n wá sọ́dọ̀ mi láti Babeli.”
- Isaiah 39:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wòlíì náà sì béèrè pé, “Kí ni wọ́n rí nínú ààfin rẹ?” Hesekiah si dáhùn pe, “Wọ́n rí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin mi. Kò sí ohun kankan nínú ìṣúra mi tí èmi kò fihàn wọ́n.”
- Isaiah 39:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn náà ni Isaiah sọ fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
- Isaiah 39:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àsìkò ń bọ̀ nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà nínú ààfin rẹ, àti ohun gbogbo tí àwọn baba rẹ ti kójọ títí di ọjọ́ òní yóò di kíkó lọ sí Babeli. Ohun kankan kò ní ṣẹ́kù ni Olúwa wí.
- Isaiah 39:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àti díẹ̀ nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ, àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara rẹ tí a ó bí fún ọ ni a ó kó lọ, wọn yóò sì di ìwẹ̀fà nínú ààfin ọba Babeli.”
- Isaiah 39:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Hesekiah wí fún Isaiah pé, “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Àlàáfíà àti ààbò yóò wà ní ìgbà ayé tèmi.”
- Isaiah 40:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí.
- Isaiah 40:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
- Isaiah 40:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.
- Isaiah 40:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbogbo àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ.
- Isaiah 40:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀, gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”
- Isaiah 40:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.” Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
- Isaiah 40:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
- Isaiah 40:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”
- Isaiah 40:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”