- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 23:3nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá; ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire, òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè.
- Isaiah 23:4nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun, nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀. “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
- Isaiah 23:5nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti, wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti Tire.
- Isaiah 23:6nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Kọjá wá sí Tarṣiṣi; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
- Isaiah 23:7nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín, ògbólógbòó ìlú náà, èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
- Isaiah 23:8nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Ta ló gbèrò èyí sí Tire, ìlú aládé, àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé?
- Isaiah 23:9nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀.
- Isaiah 23:10nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti, ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
- Isaiah 23:11nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
- Isaiah 23:12nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́, ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
- Isaiah 23:13nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.
- Isaiah 23:14nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!
- Isaiah 23:15nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:
- Isaiah 23:16nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
“Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.”
- Isaiah 23:17nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé.
- Isaiah 23:18nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi
Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.
- Isaiah 24:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé yóò sì pa á run òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́ yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
- Isaiah 24:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
bákan náà ni yóò sì rí fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn, fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀, fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin, fún olùtà àti olùrà, fún ayáni àti atọrọ fún ayánilówó àti onígbèsè.
- Isaiah 24:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.
- Isaiah 24:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá, ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un, àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
- Isaiah 24:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́; wọ́n ti pa àwọn òfin run wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
- Isaiah 24:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run; àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn. Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù, àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
- Isaiah 24:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ, gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
- Isaiah 24:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́ ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
- Isaiah 24:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́ ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.