Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 22:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ; a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà. Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀, lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà lọ́nà jíjìn réré.

  2. Isaiah 22:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi: jẹ́ kí n sọkún kíkorò. Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”

  3. Isaiah 22:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan tí rúkèrúdò àti rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ní àfonífojì ìmọ̀, ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀ àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.

  4. Isaiah 22:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.

  5. Isaiah 22:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.

  6. Isaiah 22:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò. Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù.

  7. Isaiah 22:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀, ìwọ ti tọ́jú omi sínú adágún ti ìsàlẹ̀.

  8. Isaiah 22:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.

  9. Isaiah 22:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì fún omi inú adágún àtijọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀ tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.

  10. Isaiah 22:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti sọkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.

  11. Isaiah 22:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

  12. Isaiah 22:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

  13. Isaiah 22:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé, fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

  14. Isaiah 22:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

  15. Isaiah 22:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.

  16. Isaiah 22:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!

  17. Isaiah 22:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

  18. Isaiah 22:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah.

  19. Isaiah 22:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda.

  20. Isaiah 22:22nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí.

  21. Isaiah 22:23nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀.

  22. Isaiah 22:24nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.

  23. Isaiah 22:25nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

  24. Isaiah 23:1nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi! Nítorí a ti pa Tire run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

  25. Isaiah 23:2nǹkan bí 715 ṣáájú Kristi

    Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni, ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.