- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 25:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀ wọn yóò sì wà nílẹ̀, Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀, àní sí erùpẹ̀ lásán.
- Isaiah 26:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda. Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀.
- Isaiah 26:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́.
- Isaiah 26:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
- Isaiah 26:4nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa títí láé, nítorí Olúwa, Olúwa ni àpáta ayérayé náà.
- Isaiah 26:5nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
- Isaiah 26:6nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹsẹ̀ aninilára n nì, ipasẹ̀ àwọn òtòṣì.
- Isaiah 26:7nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú, ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere.
- Isaiah 26:8nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
- Isaiah 26:9nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
- Isaiah 26:10nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti sọ òdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.
- Isaiah 26:11nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.
- Isaiah 26:12nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa; ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni ó ṣe é fún wa.
- Isaiah 26:13nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí, ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
- Isaiah 26:14nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́; gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́. Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán, ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.
- Isaiah 26:15nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa; ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i. Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ; ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
- Isaiah 26:16nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Olúwa, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njú wọn; nígbà tí ìbáwí rẹ wà lára wọn, wọ́n gbàdúrà kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
- Isaiah 26:17nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ̀ bímọ tí í rúnra tí ó sì ń sọkún nínú ìrora rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájú rẹ Olúwa.
- Isaiah 26:18nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìrora, ṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ. Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé; àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.
- Isaiah 26:19nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n àwọn òkú yín yóò wà láààyè ara wọn yóò dìde. Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀, dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀. Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀, ayé yóò bí àwọn òkú rẹ̀ lọ́mọ.
- Isaiah 26:20nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wù yín lọ kí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn yín, ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀ títí tí ìbínú rẹ̀ yóò fi rékọjá.
- Isaiah 26:21nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀; kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.
- Isaiah 27:1nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì; Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.
- Isaiah 27:2nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
- Isaiah 27:3nǹkan bí 712 ṣáájú Kristi
Èmi Olúwa ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.