Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 11:6nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Bẹtilẹhẹmu, Etamu, Tekoa,

  2. 2 Kronika 11:7nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Beti-Suri, Soko, Adullamu,

  3. 2 Kronika 11:8nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Gati, Meraṣa Sifi,

  4. 2 Kronika 11:9nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Adoraimu, Lakiṣi, Aseka

  5. 2 Kronika 11:10nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Sora, Aijaloni, àti Hebroni. Wọ̀nyí ni àwọn ìlú ìdáàbòbò ní Juda àti Benjamini.

  6. 2 Kronika 11:11nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì.

  7. 2 Kronika 11:12nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀.

  8. 2 Kronika 11:13nǹkan bí 974 ṣáájú Kristi

    Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákèjádò Israẹli wà ní ẹ̀bá rẹ̀.

  9. 2 Kronika 11:14nǹkan bí 974 ṣáájú Kristi

    Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.

  10. 2 Kronika 11:15nǹkan bí 974 ṣáájú Kristi

    Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, àti fún àwọn ère òbúkọ, àti fún ẹgbọrọ màlúù tí ó ṣe.

  11. 2 Kronika 11:16nǹkan bí 974 ṣáájú Kristi

    Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn.

  12. 2 Kronika 11:17nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí.

  13. 2 Kronika 11:18nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.

  14. 2 Kronika 11:19nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jeuṣi, Ṣemariah àti Sahamu.

  15. 2 Kronika 11:20nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, tí ó bí Abijah fún Attai, Sisa àti Ṣelomiti.

  16. 2 Kronika 11:21nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Rehoboamu fẹ́ràn Maaka ọmọbìnrin Absalomu ju èyíkéyìí nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.

  17. 2 Kronika 11:22nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Rehoboamu yan Abijah ọmọ Maaka láti jẹ́ olóyè ọmọ-aládé láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.

  18. 2 Kronika 11:23nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́n díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ká àwọn agbègbè Juda àti Benjamini àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.

  19. 2 Kronika 12:1nǹkan bí 972 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí a fi ìjọba Rehoboamu múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba, tí ó sì ti di alágbára, òun àti gbogbo Israẹli, pẹ̀lú rẹ̀ ni wọ́n pa òfin Olúwa tì.

  20. 2 Kronika 12:2nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Nítorí tí wọn kò ṣọ òtítọ́ sí Olúwa. Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu ní ọdún karùn-ún ti ọba Rehoboamu.

  21. 2 Kronika 12:3nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ẹgbàá mẹ́fà (12,000) kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta (60,000) àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Libia, Sukki àti Kuṣi, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Ejibiti.

  22. 2 Kronika 12:4nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Juda, pẹ̀lú wá sí Jerusalẹmu bí ó ti jìnnà tó.

  23. 2 Kronika 12:5nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, wòlíì Ṣemaiah wá sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Juda tí wọ́n ti péjọ ní Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù Ṣiṣaki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣiṣaki.”

  24. 2 Kronika 12:6nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Àwọn olórí Israẹli àti ọba rẹ̀ ará wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Olódodo ni Olúwa.”

  25. 2 Kronika 12:7nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Olúwa rí i pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa yí tọ Ṣemaiah lọ pé, “Níwọ́n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jerusalẹmu ní ipasẹ̀ Ṣiṣaki.