Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Ọba 25:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,

  2. 2 Ọba 25:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    wọ́n sì mú un. Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀.

  3. 2 Ọba 25:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.

  4. 2 Ọba 25:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún kọkàndínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu;

  5. 2 Ọba 25:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun.

  6. 2 Ọba 25:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀.

  7. 2 Ọba 25:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà.

  8. 2 Ọba 25:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko.

  9. 2 Ọba 25:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn ará Babeli fọ́ ọ̀wọ̀n idẹ wọ̀n-ọn-nì àti àwọn ìjókòó wọ̀n-ọn-nì, àti agbada idẹ títóbi wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ilé Olúwa, àwọn ará Babeli fọ́ túútúú, wọ́n sì kó idẹ náà lọ sí Babeli.

  10. 2 Ọba 25:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì kó àwọn ìkòkò wọ̀n-ọn-nì, ọkọ́ wọ̀n-ọn-nì, ọ̀pá fìtílà wọ̀n-ọn-nì, síbí wọ̀n-ọn-nì àti gbogbo ohun èlò idẹ wọ̀n-ọn-nì tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lọ.

  11. 2 Ọba 25:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Olórí ẹ̀ṣọ́ kó ohun ìfọnná wọ̀n-ọn-nì, àti ọpọ́n wọ̀n-ọn-nì, èyí tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

  12. 2 Ọba 25:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọ̀wọ́n méjì, agbada ńlá kan, àti ìjókòó wọ̀n-ọn-nì tí Solomoni ti ṣe fún ilé Olúwa, idẹ ni gbogbo ohun èló wọ̀nyí, ó ju èyí tí a lé wọ́n lọ.

  13. 2 Ọba 25:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Gíga ọ̀wọ́n kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún, àti ọnà-orí rẹ̀ idẹ ni: àti gíga ọnà-orí náà ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta; àti iṣẹ́ híhun náà, àti àwọn pomegiranate tí ó wà lórí ọnà-orí náà yíká, gbogbo rẹ̀ ti idẹ ni: gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́n yìí sì ni ọ̀wọ́n kejì pẹ̀lú iṣẹ́ híhun.

  14. 2 Ọba 25:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ sì mú gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, Seraiah olórí àwọn àlùfáà, Sefaniah àlùfáà kejì, àti àwọn olùṣọ́ ìloro mẹ́ta.

  15. 2 Ọba 25:19nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Àti àwọn tí ó kù ní ìlú, ó mú ìwẹ̀fà kan tí ó fi se olórí àwọn ológun, àti ọkùnrin márùn-ún nínú àwọn tó ń gba ọba ní ìmọ̀ràn. Ó sì tún mú akọ̀wé olórí ogun, tí ó ń to àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti ọgọ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú.

  16. 2 Ọba 25:20nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla.

  17. 2 Ọba 25:21nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Níbẹ̀ ní Ribla, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babeli sì kọlù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

  18. 2 Ọba 25:22nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda.

  19. 2 Ọba 25:23nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn.

  20. 2 Ọba 25:24nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”

  21. 2 Ọba 25:25nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù Gedaliah àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará Juda àti àwọn ará Babeli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mispa.

  22. 2 Ọba 25:26nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi

    Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si Ejibiti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Babeli.

  23. 2 Ọba 25:27nǹkan bí 562 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹtàdínlógójì ìgbèkùn Jehoiakini ọba Juda, ní oṣù kejìlá, ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n oṣù, Efili-Merodaki ọba Babeli, ní ọdún tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ kúrò nínú túbú.

  24. 2 Ọba 25:28nǹkan bí 562 ṣáájú Kristi

    Ó ń sọ̀rọ̀ rere fún un, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba tókù lọ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Babeli.

  25. 2 Ọba 25:29nǹkan bí 562 ṣáájú Kristi

    Ó sì pàrọ̀ àwọn aṣọ túbú rẹ̀, ó sì ń jẹun ní gbogbo ìgbà ní iwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.