Skip to content

Jehoshaphat

69 ẹsẹ · 9 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Josaphat

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jehoshaphat

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Asa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, Jehoṣafati ọba Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti rí ọba Israẹli.

  3. Ó sì béèrè lọ́wọ́ Jehoṣafati pé, “Ṣé ìwọ yóò bá mi lọ láti lọ bá Ramoti Gileadi jà?” Jehoṣafati sì dá ọba Israẹli lóhùn pé, “Èmi bí ìwọ, ènìyàn mi bí ènìyàn rẹ, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

  4. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati sì tún wí fún ọba Israẹli pé, “Kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.”

  5. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati béèrè pé, “Ǹjẹ́ wòlíì Olúwa kan kò sí níhìn-ín, tí àwa ìbá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”

  6. Ọba Israẹli dá Jehoṣafati lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣì wà, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa lè béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀ nítorí kì í sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere kan nípa mi, bí kò ṣe ibi. Mikaiah ọmọ Imla ni.” Jehoṣafati sì wí pé, “Kí ọba má ṣe sọ bẹ́ẹ̀.”

  7. Ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda jókòó lórí ìtẹ́ wọn, wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà wọn ní ìta ẹnu ibodè Samaria, gbogbo àwọn wòlíì náà sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.

  8. Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún ọ pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìre kan sí mi rí bí kò ṣe ibi?”

  9. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati ọba Juda gòkè lọ sí Ramoti Gileadi.

  10. Ọba Israẹli sì wí fún Jehoṣafati pé, “Èmi yóò pa aṣọ dà, èmi yóò sì lọ sí ojú ìjà, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wọ aṣọ ìgúnwà rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli pa aṣọ dà, ó sì lọ sí ojú ìjà.

  11. Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ sì rí Jehoṣafati, wọ́n sì wí pé, “Dájúdájú ọba Israẹli ni èyí.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà láti bá a jà, ṣùgbọ́n nígbà tí Jehoṣafati sì kígbe sókè,

  12. Jehoṣafati ọmọ Asa, sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba lórí Juda ní ọdún kẹrin Ahabu ọba Israẹli.

  13. Jehoṣafati sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba ọmọbìnrin Silihi.

  14. Jehoṣafati sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ọba Israẹli.

  15. Ní ti ìyókù ìṣe Jehoṣafati àti ìṣe agbára rẹ̀ tí ó ṣe, àti bí ó ti jagun sí, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda?

  16. Jehoṣafati kan ọkọ̀ Tarṣiṣi láti lọ sí Ofiri fún wúrà, ṣùgbọ́n wọn kò lọ, nítorí àwọn ọkọ̀ náà fọ́ ní Esioni-Geberi.

  17. Ní ìgbà náà Ahasiah ọmọ Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ nínú ọkọ̀,” ṣùgbọ́n Jehoṣafati kọ̀.

  18. Nígbà náà ni Jehoṣafati sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi, baba rẹ. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  19. Ahasiah ọmọ Ahabu bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria ní ọdún kẹtàdínlógún Jehoṣafati ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ọdún méjì lórí Israẹli.

  20. Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda.

  21. Jehoramu ọmọ Ahabu sì di ọba Israẹli ní Samaria ní ọdún kejìdínlógún ti Jehoṣafati ọba Juda, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjìlá.

  22. Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Moabu jà?” Ọba Juda sì dáhùn pé, “Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ. Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”

  23. Ṣùgbọ́n Jehoṣafati sì wí pé, “Ṣé kò sí wòlíì Olúwa níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Israẹli dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati wà níbí. Ó máa sábà bu omi sí ọwọ́ Elijah.”

  24. Jehoṣafati wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati àti ọba Edomu sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ.

  25. Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jehoṣafati ọba Juda, èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ.