Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 12:8nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Bí ó ti wù kí ó rí, wọn yóò sìn ní abẹ́ rẹ̀, kí wọn kí ó lè mọ̀ ìyàtọ̀ láàrín sí sìn mí àti sí sin àwọn ọba ilẹ̀ mìíràn.”

  2. 2 Kronika 12:9nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Ṣiṣaki ọba Ejibiti dojúkọ Jerusalẹmu, ó gbé àwọn ìṣúra ilé Olúwa, àti àwọn ìṣúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Solomoni dá.

  3. 2 Kronika 12:10nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni, ọba Rehoboamu dá àwọn àpáta idẹ láti fi dípò wọn, ó sì fi èyí lé àwọn alákòóso àti olùṣọ́ tí ó wà ní ẹnu iṣẹ́ ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà ààfin ọba lọ́wọ́.

  4. 2 Kronika 12:11nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Ìgbàkígbà tí ọba bá lọ sí ilé Olúwa, àwọn olùṣọ́ n lọ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn àpáta náà àti lẹ́yìn, wọ́n dá wọn padà sí yàrá ìṣọ́.

  5. 2 Kronika 12:12nǹkan bí 970 ṣáájú Kristi

    Nítorí ti Rehoboamu rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìbínú Olúwa yí padà kúrò lórí rẹ̀, a kò sì pa á run pátápátá. Nítòótọ́, ìre díẹ̀ wà ní Juda.

  6. 2 Kronika 12:13nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Ọba Rehoboamu fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jerusalẹmu, ó sì tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí Olúwa ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Ammoni.

  7. 2 Kronika 12:14nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    O sì ṣe búburú, nítorí tí kò múra nínú ọkàn rẹ̀ láti wá Olúwa.

  8. 2 Kronika 12:15nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Fún tí iṣẹ́ ìjọba Rehoboamu láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrántí ti Ṣemaiah wòlíì àti ti Iddo, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀síwájú ogun jíjà sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu.

  9. 2 Kronika 12:16nǹkan bí 975 ṣáájú Kristi

    Rehoboamu sun pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sin ín sínú ìlú ńlá ti Dafidi. Abijah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  10. 2 Kronika 13:1nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Jeroboamu, Abijah di ọba Juda.

  11. 2 Kronika 13:2nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Mikaiah, ọmọbìnrin Urieli ti Gibeah. Ogun wà láàrín Abijah àti Jeroboamu.

  12. 2 Kronika 13:3nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Abijah lọ sí ojú ogun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun ogún ọ̀kẹ́ (400,000) ọkùnrin alágbára, Jeroboamu kó ogun jọ pẹ̀lú ogójì ọ̀kẹ́ (800,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.

  13. 2 Kronika 13:4nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Abijah dúró lórí òkè Semaraimu ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, ó sì wí pé, Jeroboamu àti gbogbo Israẹli, ẹ gbọ́ mi!

  14. 2 Kronika 13:5nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti fún Dafidi àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ni oyè ọba títí láé nípasẹ̀ májẹ̀mú iyọ̀?

  15. 2 Kronika 13:6nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, oníṣẹ́ Solomoni ọmọ Dafidi, ṣọ̀tẹ̀ sí ọ̀gá rẹ̀.

  16. 2 Kronika 13:7nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.

  17. 2 Kronika 13:8nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    “Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín.

  18. 2 Kronika 13:9nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Olúwa jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run.

  19. 2 Kronika 13:10nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    “Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

  20. 2 Kronika 13:11nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

  21. 2 Kronika 13:12nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”

  22. 2 Kronika 13:13nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, Jeroboamu ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà níwájú Juda, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn.

  23. 2 Kronika 13:14nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Juda sì bojú wo ẹ̀yìn, sì kíyèsi i, ogun ń bẹ níwájú àti lẹ́yìn, wọn sì ké pe Olúwa, àwọn àlùfáà sì fun ìpè.

  24. 2 Kronika 13:15nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Olúkúlùkù, ọkùnrin Juda sì fún ìpè ogun, ó sì ṣe, bí àwọn ọkùnrin Juda sì ti fun ìpè ogun, ni Ọlọ́run kọlu Jeroboamu àti gbogbo Israẹli níwájú Abijah àti Juda.

  25. 2 Kronika 13:16nǹkan bí 958 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sálọ kúrò níwájú Juda, Ọlọ́run sì fi wọ́n lé wọn lọ́wọ́.