- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Kọrinti 8:4nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.
- 1 Kọrinti 8:5nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa).
- 1 Kọrinti 8:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.
- 1 Kọrinti 8:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́.
- 1 Kọrinti 8:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.
- 1 Kọrinti 8:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀.
- 1 Kọrinti 8:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà?
- 1 Kọrinti 8:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún.
- 1 Kọrinti 8:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ.
- 1 Kọrinti 8:13nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.
- 1 Kọrinti 9:1nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe aposteli bí? Èmi kò ha ti rí Jesu Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí?
- 1 Kọrinti 9:2nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe aposteli. Dájúdájú aposteli ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ aposteli mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.
- 1 Kọrinti 9:3nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ aposteli mi.
- 1 Kọrinti 9:4nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?
- 1 Kọrinti 9:5nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í ṣe onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn aposteli mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kefa.
- 1 Kọrinti 9:6nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ṣé èmi nìkan àti Barnaba, àwa kò ha ní agbára láti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa ni?
- 1 Kọrinti 9:7nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ta ni ó ṣíṣẹ́ ológun tí ó sanwó ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀? Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́ ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́ ẹran?
- 1 Kọrinti 9:8nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì?
- 1 Kọrinti 9:9nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mose, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?
- 1 Kọrinti 9:10nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a ṣe kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìrètí láti ní ìpín nínú ìkórè.
- 1 Kọrinti 9:11nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí àwa ti fún irúgbìn ohun ti ẹ̀mí sínú ọkàn yín, ohun ńlá ha ni bí àwa ó ba ká ohun ti yín tí ṣe ti ara?
- 1 Kọrinti 9:12nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù? Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má ba à ṣe ìdènà fún ìyìnrere Kristi.
- 1 Kọrinti 9:13nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, láti fi ṣe ìtọ́jú ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa ṣe àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.
- 1 Kọrinti 9:14nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù ìyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ nípa ìyìnrere.
- 1 Kọrinti 9:15nǹkan bí 59 lẹ́yìn Kristi
Síbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo irú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ ìwé yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ògo tí mo ní láti wàásù nù.