Fò sí àkóónú

circa 2100–1900 BC

Abraham: The Covenant

God calls Abram from Ur, establishes an everlasting covenant, and promises a son through whom all nations will be blessed.

394 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 23:3nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Abrahamu sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hiti wí pé,

  2. Gẹnẹsisi 23:4nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    “Èmi jẹ́ àtìpó àti àlejò láàrín yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

  3. Gẹnẹsisi 23:5nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Hiti dá Abrahamu lóhùn pé,

  4. Gẹnẹsisi 23:6nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrín wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dára jù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dù ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”

  5. Gẹnẹsisi 23:7nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Abrahamu dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà, àwọn ará Hiti.

  6. Gẹnẹsisi 23:8nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Efroni ọmọ Sohari,

  7. Gẹnẹsisi 23:9nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    kí ó ta ihò àpáta Makpela tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrín yín.”

  8. Gẹnẹsisi 23:10nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Efroni ará Hiti sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Abrahamu lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú,

  9. Gẹnẹsisi 23:11nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    pé, “Rárá, olúwa mi. Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ síbẹ̀.”

  10. Gẹnẹsisi 23:12nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Abrahamu sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà,

  11. Gẹnẹsisi 23:13nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    ó sì wí fún Efroni lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi síbẹ̀.”

  12. Gẹnẹsisi 23:14nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Efroni sì dá Abrahamu lóhùn pé,

  13. Gẹnẹsisi 23:15nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    “Gbọ́ tèmi Olúwa mi, irinwó (400) òsùwọ̀n owó fàdákà ni ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n kín ni ìyẹn já mọ láàrín àwa méjèèjì? Sá à sin òkú rẹ.”

  14. Gẹnẹsisi 23:16nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò.

  15. Gẹnẹsisi 23:17nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú,

  16. Gẹnẹsisi 23:18nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.

  17. Gẹnẹsisi 23:19nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani.

  18. Gẹnẹsisi 23:20nǹkan bí 1860 ṣáájú Kristi

    Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.

  19. Gẹnẹsisi 24:1nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà,

  20. Gẹnẹsisi 24:2nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Abrahamu wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi.

  21. Gẹnẹsisi 24:3nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé.

  22. Gẹnẹsisi 24:4nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”

  23. Gẹnẹsisi 24:5nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ń kọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?”

  24. Gẹnẹsisi 24:6nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.”

  25. Gẹnẹsisi 24:7nǹkan bí 1857 ṣáájú Kristi

    “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.