Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín.

  2. Esau sì mú àwọn aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ àti àwọn ẹran ọ̀sìn mìíràn àti gbogbo ohun ìní mìíràn tí ó ní, ni Kenaani, ó sì kó lọ sí ilẹ̀ mìíràn, jìnà sí ibi tí Jakọbu arákùnrin rẹ̀ wà.

  3. Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

  4. Jakọbu sì gbé ilẹ̀ Kenaani ní ibi ti baba rẹ̀ ti gbé.

  5. Èyí ni àwọn ìtàn Jakọbu. Nígbà tí Josẹfu di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, ó ń ṣọ́ agbo ẹran pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Biliha àti Silipa aya baba rẹ̀ Josẹfu sì ń ròyìn àwọn aburú tí wọ́n ń ṣe fún baba wọn.

  6. Israẹli sì fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ tókù lọ, nítorí ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ ni ó bí i. O sì dá aṣọ aláràbarà tí ó kún fún onírúurú ọnà lára fún un.

  7. Israẹli sì wí fún Josẹfu pé, “Ṣé o mọ̀ pé, àwọn arákùnrin rẹ ń da ẹran ní Ṣekemu, wá, jẹ́ kí n rán ọ sí wọn.” Josẹfu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  8. Nígbà náà ni Jakọbu fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ó sì ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.

  9. Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?”

  10. Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i.

  11. Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.

  12. Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé,

  13. Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!”

  14. Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”

  15. Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú.

  16. Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi

  17. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú.

  18. Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

  19. Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́.

  20. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ.

  21. Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

  22. Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀.

  23. Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  24. Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀.

  25. Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.