Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Isaaki àti Jakọbu, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀,

  2. Nípa ìgbàgbọ́ ní Isaaki súre fún Jakọbu àti Esau ní ti ohun tí ń bọ̀.

  3. Nípa ìgbàgbọ́ ni Jakọbu, nígbà tí o ń ku lọ, ó súre fún àwọn ọmọ Josẹfu ni ọ̀kọ̀ọ̀kan; ó sì sinmi ní ìtẹríba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

  4. Nípa ìgbàgbọ́ ni Josẹfu, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Israẹli; ó sì pàṣẹ ní ti àwọn egungun rẹ̀.

  5. Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.

  6. Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si, àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.

  7. Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli.