Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Temptation

346 ẹsẹ · 52 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

  2. Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá; nítorí àwa tìkára wa pẹ̀lú a máa dáríjì olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè, Má sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni búburú ni.’ ”

  3. “Ẹ di àmùrè yín, kí fìtílà yín sì máa jó.

  4. Kí ẹ̀yin tìkára yín dàbí ẹni tí ń retí olúwa wọn, nígbà tí òun ó padà ti ibi ìgbéyàwó dé, pé nígbà tí ó bá dé, tí ó sì kànkùn, kí wọn lè ṣí i sílẹ̀ fún un lọ́gán.

  5. Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà nígbà tí olúwa náà bá dé tí yóò bá wọn tí wọn ń ṣọ́nà; lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò di ara rẹ̀ ní àmùrè yóò sì mú wọn jókòó láti jẹun, yóò sì jáde wá láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

  6. Bí olúwa wọn bá sì dé nígbà ìṣọ́ kejì, tàbí tí ó sì dé nígbà ìṣọ́ kẹta, tí ó sì bá wọn bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà.

  7. Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

  8. “Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsára yín, kí ọkàn yín má ṣe kún fún wọ̀bìà, àti fún ọtí àmupara, àti fún àníyàn ayé yìí, tí ọjọ́ náà yóò sì fi dé bá yín lójijì bí ìkẹ́kùn.

  9. Nítorí bẹ́ẹ̀ ni yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé orí gbogbo ilẹ̀ ayé.

  10. Ǹjẹ́ kì ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ ba à lè la gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí yóò ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ Ènìyàn.”

  11. Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá.

  12. Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama.

  13. Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

  14. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

  15. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwò.”

  16. Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;

  17. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má ba à mú yín yapa kúrò.

  18. Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sinagọgu: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run.

  19. Èmi kò gbàdúrà pé, kí ìwọ kí ó mú wọn kúrò ní ayé, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó pa wọ́n mọ́ kúrò nínú ibi.

  20. Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.

  21. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára.

  22. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

  23. Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú.

  24. Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà?

  25. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́; À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”