Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Temptation: Resistance to temptation

121 ẹsẹ · 52 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Resistance to temptation

Sẹ́ nípa ìwé
  1. lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, aya rẹ̀ ṣe àkíyèsí Josẹfu, ó sì wí fún un pé, “Wá bá mi lòpọ̀!”

  2. Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́.

  3. Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?”

  4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

  5. Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.

  6. “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú, èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá?

  7. “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,

  8. (jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)

  9. Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́,

  10. ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú-ọmọ mi tu.

  11. “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,

  12. kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.

  13. Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní, ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀.

  14. Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.

  15. “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;

  16. kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?

  17. Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?

  18. “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì,

  19. tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;

  20. bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí tálákà kan láìní ìbora;

  21. bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi;

  22. bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,

  23. ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.

  24. Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi, àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.

  25. “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’