- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Syria
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.
Ọba Asiria mú àwọn ènìyàn láti Babeli, Kuta, Afa, Hamati àti Sefarfaimi, wọ́n sì fi wọ́n sínú ìlú Samaria láti rọ́pò àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n sì ń gbé ní ìlú náà.
Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah, àti Ṣebna àti Joah sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Aramaiki, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Heberu ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”
Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.
Àwọn ọmọ Ṣemu ni: Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu. Àwọn ọmọ Aramu: Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.
(Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.) Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri baba Gileadi.
Àti ní àkókò ìjọba Artasasta ọba Persia, Biṣilami, Mitredati, Tabeli àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Artasasta. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Aramaiki èdè Aramaiki sì ní a fi kọ ọ́.
nítorí Damasku ni orí Aramu, orí Damasku sì ni Resini. Láàrín ọdún márùnlélọ́gọ́ta Efraimu yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.
Orí Efraimu sì ni Samaria, orí Samaria sì ni ọmọ Remaliah. Bí ẹ̀yin kí yóò bá gbàgbọ́, lóòtítọ́, a kì yóò fi ìdí yín múlẹ̀.’ ”
Bákan náà Olúwa tún bá Ahasi sọ̀rọ̀,
“Béèrè fún àmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jì jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ.”
Ṣùgbọ́n Ahasi sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”
Lẹ́yìn náà Isaiah sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsin yìí, ìwọ ilé Dafidi, kò ha tọ́ láti tán ènìyàn ní sùúrù, ìwọ yóò ha tan Ọlọ́run ní sùúrù bí?
Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli.
Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan rere.
Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.
Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”
Olúwa sì tún sọ fún mi pé,
“Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini àti ọmọ Remaliah,
ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le, tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn, àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀, yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku: “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí. “Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn ìlú Juda.