Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Syria: Originally included Mesopotamia

4 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Originally included Mesopotamia

  1. Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.

  3. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

  4. Ní ìdáhùn sí èyí ó wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin àti ẹ̀yin baba, ẹ fetísílẹ̀ sí mi! Ọlọ́run ògo fi ara hàn fún Abrahamu baba wa, nígbà tí ó wà ni Mesopotamia, kí ó to ṣe àtìpó ni Harani.