Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Syria: A saviour raised up for Israel against

4 ẹsẹ · 61 abala

Àwọn ẹsẹ nípa A saviour raised up for Israel against

  1. Olúwa pèsè olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣàánú fún wọn ó sì ní ìyọ́nú, ó sì fiyèsí wọn nítorí májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu. Títí di ọjọ́ òní, kì í ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ láti pa wọ́n run tàbí lé wọn lọ níwájú rẹ̀.

  3. Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  4. Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.